Submit Lyrics to wikilyrics

CACGHB Yoruba Hymn 2 Ife Orun Alailegbe


1. Ife orun alali’egbe,

   Ayo orun sokale,

   Fi okan wa se ‘bugbe Re,

   Se asetan anu Re.

2. Jesu Iwo ni alanu

   Iwo l’onibu ife

   Fi igbala Re be wa wo

   M’okan eru wa duro

3. Wa, Olodumare, gba wa

   Fun wa l’ore-ofe Re.

   L’ojiji ni k’o pada wa,

   Ma si fi wa sile mo;

4. Iwo l’a o ma yin titi,


   Bi won ti’nse ni orun

   Iyin wa ki yoo lopin

   A o s’ogo n’nu ‘fe Re.

5. S’asepe awa eda Re

   Je k’awa lailabawon

   K’a ri titobi ‘gbala Re

   Li aritan ninu Re.

6. Mu wa lat’ogo de ogo,

   Titi di ibugbe wa;

   T’ ao fi ade wa juba Re

   N’iyanu, ife, iyin.

AMIN


Note: Please support wikilyrics by Sharing or dropping a comment here. Also, You can submit song lyrics, poem or anthem here and reach thousands of Audience!
VIEW:  CACGHB Yoruba Hymn 22 Wa ba mi gbe, ale fere le tan