Submit Lyrics to wikilyrics


CACGHB Yoruba Hymn 22 Wa ba mi gbe, ale fere le tan

Share

 Wa ba mi gbe, ale fere le tan;

   Okunkun nsu, Oluwa ba mi gbe

   Bi Oluranlowo, miran ba ye,

   Iranwo alaini, Wa ba mi gbe.

2. Ojo aye mi nsare lo s’opin

   Ayo aye nku, ogo re nwomi,

   Ayida at’ibaje ni mo n ri,

   ‘Wo ti ki yipada, wa ba mi gbe.

3. Ma wa l’eru b’Oba awon oba

   B’oninure, wa pelu ‘wosan Re,

   Ki O si ma kanu fun egbe mi,

   Wa, Ore elese, wa ba mi gbe.

4. Mo nfe O ri, ni wakati gbogbo

   Kilo le segun esu b’ore Re?

VIEW:  CACGHB Yoruba Hymn 18 Lojojumo la ngbe O ga

   Tal’o le se amona mi bi Re?

   N’nu ‘banuje at’ayo ba mi gbe.

5. Pelu ‘bukun Re, eru ko ba mi

   Ibi ko wuwo, ekun ko koro,

   Oro iku da? Segun isa da?

   Un o segun sibe, b’Iwo ba mi gbe

6. Wa ba mi gbe, ni wakati iku,

   Se ‘mole mi si toka si orun

   B’aye ti nkoja, k’ile orun mo,

   Ni yiye, ni kiju, wa ba mi gbe.

AMIN 


Note: Please support wikilyrics by Sharing or dropping a comment here. Also, You can submit song lyrics, poem or anthem here and reach thousands of Audience!