Submit Lyrics to wikilyrics

CACGHB Yoruba Hymn 24 L’oju ale ‘gba’t orun wo


1. L’oju ale ‘gba’t orun wo,

   Won gbe abirun w’odo Re,

   Oniruru ni asisan won,

   Sugbon won f’ayo lo’ le won

2. Jesu a de l’oj’ ale yi,

   A sun m’O t’awa t’arun wa,

   Bi a ko tile le ‘ri O,

   Sugbon, a mo p’O sunmo wa.

3. Olugbala, wo osi wa,

   Opo nsaisan, opo nk’edun,

   Opo ko ni ‘fe si O to.

   Opo n’ife won si tutu.

4. Opo ti ri p’asan l’aye

   Sibe nwon ko f’aye sile,


   Opo l’ore ba n’inu je,

   Sibe won ko fi O s’ore

5. Ko s’okan ninu wa t’o pe

   Gbogbo wa si ni elese,

   Awon t’o si nsin O toto

   Mo ara won ni alaipe

6. Sugbon Jesu, Olugbala,

   Eni bi awa ni ‘Wo ‘se

   ‘Wo ti ri ‘danwo bi awa

   ‘Wo si ti mo ailera wa.

7. Agbar’ owo Re wa sibe,

   Ore Re si ni agbara,

   Gbo adura ale wa yi,

   Ni anu, wo gbogbo wa san.

AMIN


Note: Please support wikilyrics by Sharing or dropping a comment here. Also, You can submit song lyrics, poem or anthem here and reach thousands of Audience!
VIEW:  CACGHB Yoruba Hymn 6: Krist' f'ogo Re ka aye